Native Bible

Deuteronomy 9:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ènìyàn náà lágbára wọ́n sì ga àní àwọn ọmọ Anaki ni wọ́n. Ẹ gbọ́ nípa wọn, ẹ sì gbọ́ tí àwọn ènìyàn ń sọ nípa wọn pé, “Ta ni ó le è dojú ìjà kọ àwọn ọmọ Anaki (òmíràn)?”

Deuteronomy 9:2 in English

Deuteronomy 9:2 · Berean Standard Bible

The people are strong and tall, the descendants of the Anakim. You know about them, and you have heard it said, “Who can stand up to the sons of Anak?”

Context

1Gbọ́, ìwọ Israẹli. Báyìí, ẹ̀yin ti gbáradì láti la Jordani kọjá, láti lọ gba ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n tóbi, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ, tí wọ́n ní àwọn ìlú ńlá ńlá, tí odi wọn kan ọ̀run. 2Àwọn ènìyàn náà lágbára wọ́n sì ga àní àwọn ọmọ Anaki ni wọ́n. Ẹ gbọ́ nípa wọn, ẹ sì gbọ́ tí àwọn ènìyàn ń sọ nípa wọn pé, “Ta ni ó le è dojú ìjà kọ àwọn ọmọ Anaki (òmíràn)?” 3Ṣùgbọ́n kí ó dá a yín lójú lónìí pé Olúwa Ọlọ́run yín ni ó ń ṣáájú u yín lọ gẹ́gẹ́ bí iná ajónirun. Yóò jó wọn run, yóò sì tẹ orí wọn ba níwájú yín. Ẹ̀yin yóò sì lé wọ́n jáde, ẹ̀yin yóò sì run wọ́n kíákíá, bí Olúwa ti ṣèlérí fún un yín. 4Lẹ́yìn tí Olúwa Ọlọ́run yín bá ti lé wọn jáde níwájú u yín, ẹ má ṣe wí fún ara yín pé, “Torí òdodo mi ní Olúwa ṣe mú mi wá síbí láti gba ilẹ̀ náà.” Rárá, ṣùgbọ́n nítorí ìwà búburú àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ni Olúwa yóò ṣe lé wọn jáde níwájú u yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.