Deuteronomi 8:13
Deuteronomy 8:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
nígbà tí àwọn agbo màlúù yín àti tí ewúrẹ́ ẹ yín bá pọ̀ sí i tán, tí fàdákà àti wúrà yín sì ń peléke sí i, tí ohun gbogbo tí ẹ ní sì ń pọ̀ sí i,
Deuteronomy 8:13 in English
Deuteronomy 8:13 · Berean Standard Bible
and when your herds and flocks grow large and your silver and gold increase and all that you have is multiplied,
Context
11Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má gbàgbé Olúwa Ọlọ́run yín, nípa kíkùnà láti pa àṣẹ rẹ̀, àwọn òfin rẹ̀, àti àwọn ìlànà rẹ̀ tí mo ń fún un yín lónìí mọ́. 12Kí ó má ba à jẹ́ pé, nígbà tí ẹ bá jẹun yó tán, tí ẹ bá kọ́ ilé tí ó dára tán, tí ẹ sí ń gbé inú rẹ̀, 13nígbà tí àwọn agbo màlúù yín àti tí ewúrẹ́ ẹ yín bá pọ̀ sí i tán, tí fàdákà àti wúrà yín sì ń peléke sí i, tí ohun gbogbo tí ẹ ní sì ń pọ̀ sí i, 14nígbà náà ni ọkàn yín yóò gbéga, tí ẹ̀yin yóò sì gbàgbé Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti wá, nínú oko ẹrú. 15Òun ni ó mú un yín la aginjù ẹlẹ́rù ńlá já, ilẹ̀ tí kò sí omi tí ó sì kún fún òǹgbẹ, pẹ̀lú àwọn ejò olóró ńlá ńlá àti àkéekèe. Ó mú omi jáde fún un yín láti inú àpáta.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.