Deuteronomi 8:12
Deuteronomy 8:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí ó má ba à jẹ́ pé, nígbà tí ẹ bá jẹun yó tán, tí ẹ bá kọ́ ilé tí ó dára tán, tí ẹ sí ń gbé inú rẹ̀,
Deuteronomy 8:12 in English
Deuteronomy 8:12 · Berean Standard Bible
Otherwise, when you eat and are satisfied, when you build fine houses in which to dwell,
Context
10Nígbà tí ẹ bá ti jẹ tí ẹ sì yó tán ẹ yin Olúwa Ọlọ́run yín fún pípèsè ilẹ̀ rere fún un yín. 11Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má gbàgbé Olúwa Ọlọ́run yín, nípa kíkùnà láti pa àṣẹ rẹ̀, àwọn òfin rẹ̀, àti àwọn ìlànà rẹ̀ tí mo ń fún un yín lónìí mọ́. 12Kí ó má ba à jẹ́ pé, nígbà tí ẹ bá jẹun yó tán, tí ẹ bá kọ́ ilé tí ó dára tán, tí ẹ sí ń gbé inú rẹ̀, 13nígbà tí àwọn agbo màlúù yín àti tí ewúrẹ́ ẹ yín bá pọ̀ sí i tán, tí fàdákà àti wúrà yín sì ń peléke sí i, tí ohun gbogbo tí ẹ ní sì ń pọ̀ sí i, 14nígbà náà ni ọkàn yín yóò gbéga, tí ẹ̀yin yóò sì gbàgbé Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti wá, nínú oko ẹrú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.