Deuteronomi 7:8
Deuteronomy 7:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n torí Olúwa fẹ́ràn yín, tí ó sì pa ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín mọ́ ni ó ṣe fi ọwọ́ agbára ńlá mú un yín jáde tí ó sì rà yín padà nínú oko ẹrú, àti láti ọwọ́ agbára Farao ọba Ejibiti.
Deuteronomy 7:8 in English
Deuteronomy 7:8 · Berean Standard Bible
But because the LORD loved you and kept the oath He swore to your fathers, He brought you out with a mighty hand and redeemed you from the house of slavery, from the hand of Pharaoh king of Egypt.
Context
6Torí pé ènìyàn mímọ́ ni ẹ jẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run yín, Olúwa Ọlọ́run yín ti yàn yín láàrín gbogbo ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé, láti jẹ́ ènìyàn rẹ̀: ohun ìní iyebíye rẹ̀. 7Olúwa kò torí pé ẹ pọ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ju àwọn ènìyàn yòókù lọ yàn yín, ẹ̀yin sá à lẹ kéré jù nínú gbogbo ènìyàn. 8Ṣùgbọ́n torí Olúwa fẹ́ràn yín, tí ó sì pa ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín mọ́ ni ó ṣe fi ọwọ́ agbára ńlá mú un yín jáde tí ó sì rà yín padà nínú oko ẹrú, àti láti ọwọ́ agbára Farao ọba Ejibiti. 9Nítorí náà ẹ mọ̀ dájúdájú pé Olúwa Ọlọ́run yín, Òun ni Ọlọ́run, Ọlọ́run olóòtítọ́ ni, tí ń pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìran, àwọn tí ó fẹ́ ẹ tí ó sì ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. 10Ṣùgbọ́n
àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ ni yóò san ẹ̀san fún ní gbangba nípa pípa wọ́n run;
kì yóò sì jáfara láti san ẹ̀san fún àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ ní gbangba.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.