Native Bible

Deuteronomy 6:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ ṣe èyí tí ó dára tí ó sì tọ́ lójú Olúwa, kí ó bá à lè dára fún un yín, kí ẹ̀yin bá à lè lọ láti gba ilẹ̀ dáradára náà tí Ọlọ́run ti fi ìbúra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá a yín.

Deuteronomy 6:18 in English

Deuteronomy 6:18 · Berean Standard Bible

Do what is right and good in the sight of the LORD, so that it may be well with you and that you may enter and possess the good land that the LORD your God swore to give your fathers,

Context

16Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run yín wò bí ẹ̀yin ti dán wò ní Massa. 17Ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń pa àwọn òfin Olúwa Ọlọ́run yín mọ́ àti àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà tí ó ti fún un yín. 18Ẹ ṣe èyí tí ó dára tí ó sì tọ́ lójú Olúwa, kí ó bá à lè dára fún un yín, kí ẹ̀yin bá à lè lọ láti gba ilẹ̀ dáradára náà tí Ọlọ́run ti fi ìbúra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá a yín. 19Ẹ̀yin yóò sì ti àwọn ọ̀tá yín jáde níwájú u yín bí Olúwa ti ṣèlérí. 20Ní ọjọ́ iwájú, bí ọmọ rẹ bá béèrè pé, “Kí ni ìtumọ̀ àwọn àṣẹ, ìlànà àti òfin wọ̀nyí tí Olúwa Ọlọ́run wa ti pàṣẹ fún ọ?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.