Deuteronomi 5:6
Deuteronomy 5:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti, láti oko ẹrú jáde wá.
Deuteronomy 5:6 in English
Deuteronomy 5:6 · Berean Standard Bible
“I am the LORD your God, who brought you out of the land of Egypt, out of the house of slavery.
Context
4Olúwa bá a yín sọ̀rọ̀ lójúkojú láàrín iná lórí òkè. 5(Ní ìgbà yìí, mo wà láàrín ẹ̀yin pẹ̀lú Ọlọ́run láti sọ ọ̀rọ̀ Olúwa fún un yín torí pé ẹ̀rù Ọlọ́run ń bà yín, ẹ kò sì lè kọjá lọ sórí òkè.)
Ó sì wí pé, 6“Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti, láti oko ẹrú jáde wá. 7“Ìwọ kò gbọdọ̀ ní ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi. 8Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ère fún ara yín, tàbí àwòrán ohun kan tí ń bẹ ní òkè ọ̀run, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ nínú omi ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.