Deuteronomi 33:19
Deuteronomy 33:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọn yóò pe àwọn ènìyàn sórí òkè àti níbẹ̀ wọn yóò rú ẹbọ òdodo, wọn yóò mu nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ Òkun, nínú ìṣúra tí ó pamọ́ nínú iyanrìn.”
Deuteronomy 33:19 in English
Deuteronomy 33:19 · Berean Standard Bible
They will call the peoples to a mountain; there they will offer sacrifices of righteousness. For they will feast on the abundance of the seas and the hidden treasures of the sand.”
Context
17Ní ọláńlá ó dàbí àkọ́bí akọ màlúù;
ìwo rẹ̀, ìwo àgbáǹréré ni.
Pẹ̀lú wọn ni yóò fi ti àwọn orílẹ̀-èdè,
pàápàá títí dé òpin ayé.
Àwọn sì ni ẹgbẹẹgbàárùn mẹ́wàá Efraimu,
àwọn sì ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún Manase.” 18Ní ti Sebuluni ó wí pé,
“Yọ̀ Sebuluni, ní ti ìjáde lọ rẹ,
àti ìwọ Isakari, nínú àgọ́ rẹ. 19Wọn yóò pe àwọn ènìyàn sórí òkè
àti níbẹ̀ wọn yóò rú ẹbọ òdodo,
wọn yóò mu nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ Òkun,
nínú ìṣúra tí ó pamọ́ nínú iyanrìn.” 20Ní ti Gadi ó wí pé,
“Ìbùkún ni ẹni tí ó mú Gadi gbilẹ̀!
Gadi ń gbé níbẹ̀ bí kìnnìún,
ó sì fa apá ya, àní àtàrí. 21Ó sì yan ilẹ̀ tí ó dára jù fún ara rẹ̀;
ìpín olórí ni a sì fi fún un.
Nígbà tí ó rí tí gbogbo àwọn ènìyàn péjọ,
ó mú òdodo Olúwa ṣẹ,
àti ìdájọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Israẹli.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.