Deuteronomi 32:21
Deuteronomy 32:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n fi mí jowú nípa ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run, wọ́n sì fi ohun asán an wọn mú mi bínú. Èmi yóò mú wọn kún fún ìlara láti ọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe ènìyàn; èmi yóò sì mú wọn bínú láti ọ̀dọ̀ aṣiwèrè orílẹ̀-èdè.
Deuteronomy 32:21 in English
Deuteronomy 32:21 · Berean Standard Bible
They have provoked My jealousy by that which is not God; they have enraged Me with their worthless idols. So I will make them jealous by those who are not a people;* I will make them angry by a nation without understanding.*
Context
19Olúwa sì rí èyí ó sì kọ̀ wọ́n,
nítorí tí ó ti bínú nítorí ìwà ìmúnibínú àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ. 20Ó sì wí pé, “Èmi yóò pa ojú mi mọ́ kúrò lára wọn,
èmi yóò sì wò ó bí ìgbẹ̀yìn in wọn yóò ti rí;
nítorí wọ́n jẹ́ ìran alágídí,
àwọn ọmọ tí kò sí ìgbàgbọ́ nínú wọn. 21Wọ́n fi mí jowú nípa ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run,
wọ́n sì fi ohun asán an wọn mú mi bínú.
Èmi yóò mú wọn kún fún ìlara láti ọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe ènìyàn;
èmi yóò sì mú wọn bínú láti ọ̀dọ̀ aṣiwèrè orílẹ̀-èdè. 22Nítorí pé iná kan ràn nínú ìbínú mi,
yóò sì jó dé ipò ikú ní ìsàlẹ̀.
Yóò sì run ayé àti ìkórè e rẹ̀
yóò sì tiná bọ ìpìlẹ̀ àwọn òkè ńlá. 23“Èmi yóò kó àwọn ohun búburú lé wọn lórí
èmi ó sì na ọfà mi tán sí wọn lára.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.