Deuteronomi 32:12
Deuteronomy 32:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa ṣamọ̀nà; kò sì sí ọlọ́run àjèjì pẹ̀lú rẹ̀.
Deuteronomy 32:12 in English
Deuteronomy 32:12 · Berean Standard Bible
The LORD alone led him, and no foreign god was with him.
Context
10Ní aginjù ni ó ti rí i,
ní aginjù níbi tí ẹranko kò sí.
Ó yíká, ó sì tọ́jú rẹ̀,
ó pa á mọ́ bí ẹyin ojú u rẹ̀. 11Bí idì ti í ru ìtẹ́ rẹ̀ ti ó sì ń
rábàbà sórí ọmọ rẹ̀,
tí ó na ìyẹ́ apá rẹ̀ láti gbé wọn ki ó sì
gbé wọn sórí ìyẹ́ apá rẹ̀. 12Olúwa ṣamọ̀nà;
kò sì sí ọlọ́run àjèjì pẹ̀lú rẹ̀. 13Ó mú gun ibi gíga ayé
ó sì fi èso oko bọ́ ọ.
Ó sì jẹ́ kí ó mú oyin láti inú àpáta wá,
àti òróró láti inú akọ òkúta wá. 14Pẹ̀lú u wàràǹkàṣì àti wàrà àgùntàn
àti ti àgbò ẹran
àti pẹ̀lú ọ̀rá ọ̀dọ́-àgùntàn àti ewúrẹ́,
pẹ̀lú àgbò irú u ti Baṣani
tí ó sì mu ẹ̀jẹ̀ èso àjàrà, àní àti wáìnì.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.