Deuteronomi 31:5
Deuteronomy 31:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa yóò fi wọ́n fún ọ, kí o sì ṣe sí wọn gbogbo èyí tí mo ti pàṣẹ fún ọ.
Deuteronomy 31:5 in English
Deuteronomy 31:5 · Berean Standard Bible
The LORD will deliver them over to you, and you must do to them exactly as I have commanded you.
Context
3Olúwa Ọlọ́run rẹ fúnra rẹ̀ ni yóò rékọjá fún ọ. Yóò pa àwọn orílẹ̀-èdè yìí run níwájú rẹ, ìwọ yóò sì mú ìní ilẹ̀ wọn, Joṣua náà yóò rékọjá fún ọ, bí Olúwa ti sọ. 4Olúwa yóò sì ṣe fún wọn ohun tí ó ti ṣe sí Sihoni àti sí Ogu ọba Amori, tí ó parun pẹ̀lú ilẹ̀ ẹ wọn. 5Olúwa yóò fi wọ́n fún ọ, kí o sì ṣe sí wọn gbogbo èyí tí mo ti pàṣẹ fún ọ. 6Jẹ́ alágbára kí o sì ní ìgboyà. Má ṣe bẹ̀rù tàbí jáyà nítorí i wọn, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń lọ pẹ̀lú rẹ, Òun kò ní fi ọ́ sílẹ̀ tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀.” 7Nígbà náà ni Mose pe Joṣua ó sì wí fún un níwájú gbogbo Israẹli pé, “Jẹ́ alágbára àti onígboyà, nítorí o ní láti lọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn wọ̀nyí sí ilẹ̀ tí Olúwa búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fún wọn, kí o sì pín ilẹ̀ náà láàrín wọn bí ogún wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.