Native Bible

Deuteronomy 31:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ péjọpọ̀ síwájú mi gbogbo àgbà ẹ̀yà yín àti àwọn aláṣẹ yín, kí èmi lè sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí etí ìgbọ́ ọ́ wọn.

Deuteronomy 31:28 in English

Deuteronomy 31:28 · Berean Standard Bible

Assemble before me all the elders of your tribes and all your officers so that I may speak these words in their hearing and call heaven and earth to witness against them.

Context

26“Gba ìwé òfin yìí kí o sì fi sí ẹ̀gbẹ́ àpótí ẹ̀rí Olúwa Ọlọ́run rẹ. Níbẹ̀ ni yóò wà bí ẹ̀rí sí ọ. 27Nítorí mo mọ irú ọlọ̀tẹ̀ àti ọlọ́rùn líle tí ẹ jẹ́. Bí o bá ṣe ọlọ̀tẹ̀ sí Olúwa nígbà tí mo pàpà wà láyé pẹ̀lú yín, báwo ní ẹ ó ti ṣe ọlọ̀tẹ̀ tó nígbà tí mo bá kú tán! 28Ẹ péjọpọ̀ síwájú mi gbogbo àgbà ẹ̀yà yín àti àwọn aláṣẹ yín, kí èmi lè sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí etí ìgbọ́ ọ́ wọn. 29Nítorí tí mo mọ̀ pé lẹ́yìn ikú mi, ó dájú pé ìwọ yóò padà di ìbàjẹ́ pátápátá, ẹ ó sì yípadà kúrò ní ọ̀nà tí mo ti pàṣẹ fún un yín. Ní ọjọ́ tó ń bọ̀, ìpọ́njú yóò sọ̀kalẹ̀ sórí i yín nítorí ẹ̀yin yóò ṣe búburú níwájú Olúwa ẹ ó sì mú u bínú nípa ohun tí ọwọ́ yín ti ṣe.” 30Mose sì ka ọ̀rọ̀ inú orin yìí láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin sí etí ìgbọ́ ọ gbogbo ìjọ Israẹli:

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.