Deuteronomi 31:25
Deuteronomy 31:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
ó sì fi àṣẹ yìí fún àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ń gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa:
Deuteronomy 31:25 in English
Deuteronomy 31:25 · Berean Standard Bible
he gave this command to the Levites who carried the ark of the covenant of the LORD:
Context
23Olúwa sì fún Joṣua ọmọ Nuni ní àṣẹ yìí: “Jẹ́ alágbára àti onígboyà, nítorí ìwọ yóò mú Israẹli wá sí ilẹ̀ tí mo ṣèlérí fún wọn lórí ìbúra, èmi fúnra à mi yóò sì wà pẹ̀lú rẹ.” 24Lẹ́yìn ìgbà tí Mose ti parí i kíkọ ọ̀rọ̀ òfin yìí sínú ìwé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, 25ó sì fi àṣẹ yìí fún àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ń gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa: 26“Gba ìwé òfin yìí kí o sì fi sí ẹ̀gbẹ́ àpótí ẹ̀rí Olúwa Ọlọ́run rẹ. Níbẹ̀ ni yóò wà bí ẹ̀rí sí ọ. 27Nítorí mo mọ irú ọlọ̀tẹ̀ àti ọlọ́rùn líle tí ẹ jẹ́. Bí o bá ṣe ọlọ̀tẹ̀ sí Olúwa nígbà tí mo pàpà wà láyé pẹ̀lú yín, báwo ní ẹ ó ti ṣe ọlọ̀tẹ̀ tó nígbà tí mo bá kú tán!
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.