Native Bible

Deuteronomy 30:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi pe ọ̀run àti ilẹ̀ láti jẹ́rìí tì yín ní òní pé, èmi fi ìyè àti ikú, ìbùkún àti ègún síwájú rẹ: nítorí náà yan ìyè, kí ìwọ kí ó lè yè, ìwọ àti irú-ọmọ rẹ,

Deuteronomy 30:19 in English

Deuteronomy 30:19 · Berean Standard Bible

I call heaven and earth as witnesses against you today that I have set before you life and death, blessing and cursing. Therefore choose life, so that you and your descendants may live,

Context

17Ṣùgbọ́n tí ọkàn an yín bá yí padà tí ìwọ kò sì ṣe ìgbọ́ràn, àti bí o bá fà, lọ láti foríbalẹ̀ fún ọlọ́run mìíràn àti sìn wọ́n, 18èmi ń sọ fún un yín lónìí yìí pé ìwọ yóò parun láìsí àní àní. O kò ní í gbé pẹ́ ní ilẹ̀ tí ìwọ ń kọjá Jordani láti gbà àti láti ní. 19Èmi pe ọ̀run àti ilẹ̀ láti jẹ́rìí tì yín ní òní pé, èmi fi ìyè àti ikú, ìbùkún àti ègún síwájú rẹ: nítorí náà yan ìyè, kí ìwọ kí ó lè yè, ìwọ àti irú-ọmọ rẹ, 20kí ìwọ kí ó le máa fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, fetísílẹ̀ sí ohùn un rẹ̀, kí o sì dúró ṣinṣin nínú rẹ̀. Nítorí Olúwa ni ìyè rẹ, yóò sì fún ọ ní ọdún púpọ̀ ní ilẹ̀ tí ó ti búra láti fi fún àwọn baba rẹ Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.