Deuteronomi 28:6
Deuteronomy 28:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìbùkún ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá wọlé, ìbùkún ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá jáde.
Deuteronomy 28:6 in English
Deuteronomy 28:6 · Berean Standard Bible
You will be blessed when you come in and blessed when you go out.
Context
4Ìbùkún ni fún ọmọ inú rẹ, àti èso ilẹ̀ rẹ, àti irú ohun ọ̀sìn rẹ àti ìbísí i màlúù rẹ àti ọmọ àgùntàn rẹ. 5Ìbùkún ni fún agbọ̀n rẹ àti fún ọpọ́n ipò ìyẹ̀fun rẹ. 6Ìbùkún ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá wọlé, ìbùkún ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá jáde. 7Olúwa yóò gbà fún ọ pé gbogbo ọ̀tá tí ó dìde sí ọ yóò bì ṣubú níwájú rẹ. Wọn yóò tọ̀ ọ́ wá ní ọ̀nà kan ṣùgbọ́n wọn yóò sá fún ọ ní ọ̀nà méje. 8Olúwa yóò rán ìbùkún sí ọ àti sí ohun gbogbo tí o bá dáwọ́ rẹ lé. Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò bùkún un fún ọ nínú ilẹ̀ tí ó ń fi fún ọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.