Deuteronomi 28:54
Deuteronomy 28:54 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọkùnrin tí àwọ̀ rẹ̀ tutù nínú yín, tí ó sì ṣe ẹlẹgẹ́, ojú rẹ̀ yóò korò sí arákùnrin rẹ̀ àti sí aya oókan àyà rẹ̀, àti sí ìyókù ọmọ rẹ̀ tí òun jẹ kù.
Deuteronomy 28:54 in English
Deuteronomy 28:54 · Berean Standard Bible
The most gentle and refined man among you will begrudge his brother, the wife he embraces,* and the rest of his children who have survived,
Context
52Wọn yóò gbógun ti gbogbo ìlú rẹ títí tí odi ìdáàbòbò gíga yẹn tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé yóò fi wó lulẹ̀. Wọn yóò gbógun ti gbogbo ìlú rẹ jákèjádò ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ. 53Ìwọ ó sì jẹ èso ọmọ inú rẹ̀, ẹran-ara àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti ti àwọn ọmọ rẹ obìnrin tí Olúwa Ọlọ́run ti fi fún ọ; nínú ìdótì náà àti nínú ìhámọ́ náà tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò há ọ mọ́. 54Ọkùnrin tí àwọ̀ rẹ̀ tutù nínú yín, tí ó sì ṣe ẹlẹgẹ́, ojú rẹ̀ yóò korò sí arákùnrin rẹ̀ àti sí aya oókan àyà rẹ̀, àti sí ìyókù ọmọ rẹ̀ tí òun jẹ kù. 55Bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fún ẹnikẹ́ni nínú ẹran-ara àwọn ọmọ rẹ̀ tí ó ń jẹ, nítorí kò sí ohun kan tí ó kù sílẹ̀ fún un nínú ìdótì náà àti ìhámọ́, tí àwọn ọ̀tá yóò fi há ọ mọ́ ní ibodè rẹ gbogbo. 56Obìnrin tí àwọ̀ rẹ̀ tutù nínú yín, tí ó sì ṣe ẹlẹgẹ́, tí kò jẹ́ dáṣà láti fi àtẹ́lẹsẹ̀ ẹ rẹ̀ kan ilẹ̀ nítorí ìkẹ́ra àti ìwà ẹlẹgẹ́, ojú u rẹ̀ yóò korò sí ọkọ oókan àyà rẹ̀, àti sí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti ọmọ rẹ̀ obìnrin,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.