Deuteronomi 28:48
Deuteronomy 28:48 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà nínú ebi àti òǹgbẹ, nínú ìhòhò àti àìní búburú, ìwọ yóò sin àwọn ọ̀tá à rẹ tí Olúwa rán sí ọ. Yóò sì fi àjàgà irin bọ̀ ọ́ ní ọrùn, títí yóò fi run ọ́.
Deuteronomy 28:48 in English
Deuteronomy 28:48 · Berean Standard Bible
you will serve your enemies the LORD will send against you in famine, thirst, nakedness, and destitution. He will place an iron yoke on your neck until He has destroyed you.
Context
46Wọn yóò jẹ́ àmì àti ìyanu fún ọ àti fún irú-ọmọ rẹ títí láé. 47Nítorí ìwọ kò sin Olúwa Ọlọ́run rẹ ní ayọ̀ àti inú dídùn ní àkókò àlàáfíà. 48Nítorí náà nínú ebi àti òǹgbẹ, nínú ìhòhò àti àìní búburú, ìwọ yóò sin àwọn ọ̀tá à rẹ tí Olúwa rán sí ọ. Yóò sì fi àjàgà irin bọ̀ ọ́ ní ọrùn, títí yóò fi run ọ́. 49Olúwa yóò mú àwọn orílẹ̀-èdè wá sí ọ láti ọ̀nà jíjìn, bí òpin ayé, bí idì ti ń bẹ́ láti orí òkè sílẹ̀, orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò gbọ́ èdè wọn. 50Orílẹ̀-èdè tí ó rorò tí kò ní ojúrere fún àgbà tàbí àánú fún ọmọdé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.