Native Bible

Deuteronomy 28:39 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ yóò gbin ọgbà àjàrà púpọ̀ ìwọ yóò sì ro wọ́n ṣùgbọ́n kò ní mú wáìnì náà tàbí kó àwọn èso jọ, nítorí kòkòrò yóò jẹ wọ́n run.

Deuteronomy 28:39 in English

Deuteronomy 28:39 · Berean Standard Bible

You will plant and cultivate vineyards, but will neither drink the wine nor gather the grapes, because worms will eat them.

Context

37Ìwọ yóò di ẹni ìyanu, àti ẹni òwe, àti ẹni ìfisọ̀rọ̀ sọ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè tí Olúwa yóò darí rẹ sí. 38Ìwọ yóò gbin irúgbìn púpọ̀ ṣùgbọ́n ìwọ yóò kórè kékeré, nítorí eṣú yóò jẹ ẹ́ run. 39Ìwọ yóò gbin ọgbà àjàrà púpọ̀ ìwọ yóò sì ro wọ́n ṣùgbọ́n kò ní mú wáìnì náà tàbí kó àwọn èso jọ, nítorí kòkòrò yóò jẹ wọ́n run. 40Ìwọ yóò ní igi olifi jákèjádò ilẹ̀ rẹ ṣùgbọ́n ìwọ kò ní lo òróró náà, nítorí olifi náà yóò rẹ̀ dànù. 41Ìwọ yóò ní àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ṣùgbọ́n ìwọ kò nípa wọ́n mọ́, nítorí wọn yóò lọ sí ìgbèkùn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.