Native Bible

Deuteronomy 28:36 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa yóò lé ọ àti ọba tí ó yàn lórí rẹ lọ sí orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò mọ̀ tàbí ti àwọn baba rẹ kò mọ̀. Ibẹ̀ ni ìwọ̀ yóò sì sin ọlọ́run mìíràn, ọlọ́run igi àti òkúta.

Deuteronomy 28:36 in English

Deuteronomy 28:36 · Berean Standard Bible

The LORD will bring you and the king you appoint to a nation neither you nor your fathers have known, and there you will worship other gods—gods of wood and stone.

Context

34Ìran tí ojú rẹ yóò rí, yóò sọ ọ́ di òmùgọ̀. 35Olúwa yóò lu eékún àti ẹsẹ̀ rẹ pẹ̀lú oówo dídùn tí kò le san tán láti àtẹ̀lé méjèèjì rẹ lọ sí òkè orí rẹ. 36Olúwa yóò lé ọ àti ọba tí ó yàn lórí rẹ lọ sí orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò mọ̀ tàbí ti àwọn baba rẹ kò mọ̀. Ibẹ̀ ni ìwọ̀ yóò sì sin ọlọ́run mìíràn, ọlọ́run igi àti òkúta. 37Ìwọ yóò di ẹni ìyanu, àti ẹni òwe, àti ẹni ìfisọ̀rọ̀ sọ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè tí Olúwa yóò darí rẹ sí. 38Ìwọ yóò gbin irúgbìn púpọ̀ ṣùgbọ́n ìwọ yóò kórè kékeré, nítorí eṣú yóò jẹ ẹ́ run.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.