Deuteronomi 27:8
Deuteronomy 27:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí o sì kọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ òfin yìí ketekete sórí òkúta tí ó ti gbé kalẹ̀.”
Deuteronomy 27:8 in English
Deuteronomy 27:8 · Berean Standard Bible
And you shall write distinctly upon these stones all the words of this law.”
Context
6Kí ìwọ kí ó mọ pẹpẹ pẹ̀lú òkúta àìgbẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí ìwọ kí ó sì máa rú ẹbọ sísun ni orí rẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ. 7Rú ẹbọ àlàáfíà níbẹ̀ kí o jẹ wọ́n, kí o sì yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ. 8Kí o sì kọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ òfin yìí ketekete sórí òkúta tí ó ti gbé kalẹ̀.” 9Nígbà náà ni Mose àti àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi, sọ fún Israẹli pé, “Ẹ dákẹ́ ẹ̀yin Israẹli, kí ẹ sì fetísílẹ̀! O ti wá di ènìyàn Olúwa Ọlọ́run rẹ báyìí. 10Gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì tẹ̀lé àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mo ń fi fún ọ lónìí.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.