Deuteronomi 27:15
Deuteronomy 27:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó fín ère tàbí gbẹ́ òrìṣà ohun tí ó jẹ́ ìríra níwájú Olúwa, iṣẹ́ ọwọ́ oníṣọ̀nà tí ó gbé kalẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
Deuteronomy 27:15 in English
Deuteronomy 27:15 · Berean Standard Bible
‘Cursed is the man who makes a carved idol or molten image—an abomination to the LORD, the work of the hands of a craftsman—and sets it up in secret.’ And let all the people say, ‘Amen!’
Context
13Àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Ebali láti gé ègún: Reubeni, Gadi, àti Aṣeri, àti Sebuluni, Dani, àti Naftali. 14Àwọn ẹ̀yà Lefi yóò ké sí gbogbo ènìyàn Israẹli ní ohùn òkè: 15“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó fín ère tàbí gbẹ́ òrìṣà ohun tí ó jẹ́ ìríra níwájú Olúwa, iṣẹ́ ọwọ́ oníṣọ̀nà tí ó gbé kalẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.”
Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!” 16“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dójútì baba tàbí ìyá rẹ̀.”
Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!” 17“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí òkúta ààlà aládùúgbò o rẹ̀.”
Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.