Deuteronomi 25:3
Deuteronomy 25:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n kò gbọdọ̀ fún un ju ogójì pàṣán lọ. Bí ó bá nà án ju bẹ́ẹ̀ lọ, arákùnrin rẹ̀ yóò di ẹni ìrẹ̀sílẹ̀ ní ojú rẹ̀.
Deuteronomy 25:3 in English
Deuteronomy 25:3 · Berean Standard Bible
He may receive no more than forty lashes, lest your brother be beaten any more than that and be degraded in your sight.
Context
1Nígbà tí àwọn ènìyàn méjì bá ń jà, kí wọn kó ẹjọ́ lọ sí ilé ìdájọ́, kí àwọn onídàájọ́ dá ẹjọ́ náà, kí wọn dá àre fún aláre àti ẹ̀bi fún ẹlẹ́bi. 2Bí ó bá tọ́ láti na ẹlẹ́bi, kí onídàájọ́ dá a dọ̀bálẹ̀ kí a sì nà án ní ojú u rẹ̀ ní iye pàṣán tí ó tọ́ sí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀. 3Ṣùgbọ́n kò gbọdọ̀ fún un ju ogójì pàṣán lọ. Bí ó bá nà án ju bẹ́ẹ̀ lọ, arákùnrin rẹ̀ yóò di ẹni ìrẹ̀sílẹ̀ ní ojú rẹ̀. 4Ìwọ kò gbọdọ̀ di màlúù ti ń tẹ ọkà lẹ́nu. 5Bí àwọn arákùnrin bá ń gbé pọ̀, tí ọ̀kan nínú wọn bá sì kú, tí kò sí ní ọmọkùnrin, kí aya òkú má ṣe ní àlejò ará òde ní ọkọ rẹ̀. Arákùnrin ọkọ rẹ̀ ni kí ó wọlé tọ̀ ọ́, kí ó fi ṣe aya, kí ó sì ṣe iṣẹ́ arákùnrin ọkọ fún un.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.