Deuteronomi 21:7
Deuteronomy 21:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
wọn yóò sì sọ pé, “Ọwọ́ wa kò ta ẹ̀jẹ̀ yìí sílẹ̀, tàbí kí ojú wa rí i ní títa sílẹ̀.”
Deuteronomy 21:7 in English
Deuteronomy 21:7 · Berean Standard Bible
and they shall declare, “Our hands did not shed this blood, nor did our eyes see it.
Context
5Àwọn àlùfáà, ọmọ Lefi yóò wá síwájú, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti yàn wọ́n láti ṣe ìránṣẹ́ fún un àti láti bùkún ní orúkọ Olúwa àti láti parí gbogbo ẹjọ́ àríyànjiyàn àti ọ̀rọ̀ ìlú. 6Nígbà náà ni gbogbo àwọn àgbàgbà ìlú tí ó wà nítòsí yóò wẹ ọwọ́ wọn lórí ẹgbọrọ abo màlúù tí a ti kan ọrùn rẹ̀ ní àfonífojì, 7wọn yóò sì sọ pé, “Ọwọ́ wa kò ta ẹ̀jẹ̀ yìí sílẹ̀, tàbí kí ojú wa rí i ní títa sílẹ̀.” 8Dáríjì, Olúwa, àwọn ènìyàn rẹ ni Israẹli, tí ìwọ ti dá sílẹ̀, àti kí ìwọ má ṣe gba ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ ní àárín àwọn ènìyàn rẹ ní Israẹli. Ṣùgbọ́n kí a dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ yìí jì. 9Nígbà náà ni ìwọ wẹ̀ kúrò láàrín rẹ ẹ̀bi títa ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí o ti ṣe èyí tí ó tọ́ níwájú Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.