Deuteronomi 21:6
Deuteronomy 21:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni gbogbo àwọn àgbàgbà ìlú tí ó wà nítòsí yóò wẹ ọwọ́ wọn lórí ẹgbọrọ abo màlúù tí a ti kan ọrùn rẹ̀ ní àfonífojì,
Deuteronomy 21:6 in English
Deuteronomy 21:6 · Berean Standard Bible
Then all the elders of the city nearest the victim shall wash their hands by the stream over the heifer whose neck has been broken,
Context
4kí àwọn àgbàgbà ìlú náà kí wọn mú ẹgbọrọ abo màlúù náà sọ̀kalẹ̀ wá sí àfonífojì tí ó ní omi ṣíṣàn kan, tí a kò ro, tí a kò sì gbìn, kí wọn kí ó sì ṣẹ́ ọrùn ẹgbọrọ màlúù náà níbẹ̀ ní àfonífojì náà. 5Àwọn àlùfáà, ọmọ Lefi yóò wá síwájú, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti yàn wọ́n láti ṣe ìránṣẹ́ fún un àti láti bùkún ní orúkọ Olúwa àti láti parí gbogbo ẹjọ́ àríyànjiyàn àti ọ̀rọ̀ ìlú. 6Nígbà náà ni gbogbo àwọn àgbàgbà ìlú tí ó wà nítòsí yóò wẹ ọwọ́ wọn lórí ẹgbọrọ abo màlúù tí a ti kan ọrùn rẹ̀ ní àfonífojì, 7wọn yóò sì sọ pé, “Ọwọ́ wa kò ta ẹ̀jẹ̀ yìí sílẹ̀, tàbí kí ojú wa rí i ní títa sílẹ̀.” 8Dáríjì, Olúwa, àwọn ènìyàn rẹ ni Israẹli, tí ìwọ ti dá sílẹ̀, àti kí ìwọ má ṣe gba ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ ní àárín àwọn ènìyàn rẹ ní Israẹli. Ṣùgbọ́n kí a dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ yìí jì.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.