Native Bible

Deuteronomy 20:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó gbin ọgbà àjàrà kan tí kò sì tí ì bẹ̀rẹ̀ sí ń gbádùn rẹ̀? Jẹ́ kí ó lọ ilé, tàbí kí ó kú sójú ogun kí ẹlòmíràn sì gbádùn rẹ̀.

Deuteronomy 20:6 in English

Deuteronomy 20:6 · Berean Standard Bible

Has any man planted a vineyard and not begun to enjoy its fruit? Let him return home, or he may die in battle and another man enjoy its fruit.

Context

4Nítorí Olúwa Ọlọ́run yín ní bá yín lọ, láti bá àwọn ọ̀tá yín jà fún yín, láti gbà yín là.” 5Àwọn olórí ogun yóò sì wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó kọ́ ilé tuntun tí kò sì tì ì yà á sọ́tọ̀? Jẹ́ kí ó lọ ilé, tàbí ó lè kú sójú ogun kí ẹlòmíràn sì gbà á. 6Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó gbin ọgbà àjàrà kan tí kò sì tí ì bẹ̀rẹ̀ sí ń gbádùn rẹ̀? Jẹ́ kí ó lọ ilé, tàbí kí ó kú sójú ogun kí ẹlòmíràn sì gbádùn rẹ̀. 7Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó wá ògo obìnrin kan tí kò ì tí ì fẹ́ ẹ? Jẹ́ kí ó lọ ilé, tàbí kí ó kú sójú ogun kí ẹlòmíràn sì fẹ́ ẹ.” 8Nígbà náà ni olórí yóò tún fi kún un pé, “Ǹjẹ́ ọkùnrin kankan ń bẹ̀rù tàbí páyà? Jẹ́ kí ó lọ ilé nítorí kí arákùnrin rẹ̀ má ba à wá tún dáyà fò ó.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.