Deuteronomi 20:2
Deuteronomy 20:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí o bá fẹ́ lọ jagun, àlùfáà yóò wá síwájú, yóò sì bá ọmọ-ogun sọ̀rọ̀,
Deuteronomy 20:2 in English
Deuteronomy 20:2 · Berean Standard Bible
When you are about to go into battle, the priest is to come forward and address the army,
Context
1Nígbà tí o bá lọ sí ogun pẹ̀lú ọ̀tá rẹ, tí o sì rí ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti ológun tí ó jù ọ́ lọ, má ṣe bẹ̀rù u wọn, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ tí ń mú ọ jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti, yóò wà pẹ̀lú rẹ. 2Nígbà tí o bá fẹ́ lọ jagun, àlùfáà yóò wá síwájú, yóò sì bá ọmọ-ogun sọ̀rọ̀, 3yóò sì wí pé, “Gbọ́, ìwọ Israẹli, lónìí ò ń jáde lọ sójú ogun sí ọ̀tá rẹ. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín ṣojo tàbí bẹ̀rù; ẹ má ṣe jáyà tàbí kí ẹ fi ààyè fún ìjayà níwájú u wọn. 4Nítorí Olúwa Ọlọ́run yín ní bá yín lọ, láti bá àwọn ọ̀tá yín jà fún yín, láti gbà yín là.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.