Native Bible

Deuteronomy 19:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá sì fẹ́ agbègbè rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìbúra fún àwọn baba ńlá a yín, tí ó sì fún ọ ní gbogbo ilẹ̀ tí ó ti ṣe ìlérí fún wọn,

Deuteronomy 19:8 in English

Deuteronomy 19:8 · Berean Standard Bible

And if the LORD your God enlarges your territory, as He swore to your fathers, and gives you all the land He promised them,

Context

6Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ lè máa lépa rẹ̀ nínú ìbínú, kí ó sì lé e bá nítorí pé ọ̀nà jì, kí ó sì pa á bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò yẹ sí ikú, nígbà tí ó ṣe é sí aládùúgbò rẹ̀ láìjẹ́ pé ó ti ní àrankàn pẹ̀lú u rẹ̀ láti ọjọ́ pípẹ́. 7Ìdí nìyìí tí mo fi pa á láṣẹ fún ọ láti ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀ fún ara rẹ. 8Tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá sì fẹ́ agbègbè rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìbúra fún àwọn baba ńlá a yín, tí ó sì fún ọ ní gbogbo ilẹ̀ tí ó ti ṣe ìlérí fún wọn, 9nítorí tí ìwọ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tẹ̀lé gbogbo òfin yìí tí mo pàṣẹ fún ọ lónìí yìí, kí o fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí o sì rìn ní ọ̀nà an rẹ̀ ní gbogbo ìgbà náà, kí o ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀. 10Ṣe èyí kí a má ṣe ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ni ilẹ̀ rẹ, èyí tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún, kí ìwọ kí ó má bá a jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ títa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.