Native Bible

Deuteronomy 19:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣe èyí kí a má ṣe ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ni ilẹ̀ rẹ, èyí tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún, kí ìwọ kí ó má bá a jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ títa.

Deuteronomy 19:10 in English

Deuteronomy 19:10 · Berean Standard Bible

Thus innocent blood will not be shed in the land that the LORD your God is giving you as an inheritance, so that you will not be guilty of bloodshed.

Context

8Tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá sì fẹ́ agbègbè rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìbúra fún àwọn baba ńlá a yín, tí ó sì fún ọ ní gbogbo ilẹ̀ tí ó ti ṣe ìlérí fún wọn, 9nítorí tí ìwọ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tẹ̀lé gbogbo òfin yìí tí mo pàṣẹ fún ọ lónìí yìí, kí o fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí o sì rìn ní ọ̀nà an rẹ̀ ní gbogbo ìgbà náà, kí o ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀. 10Ṣe èyí kí a má ṣe ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ni ilẹ̀ rẹ, èyí tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún, kí ìwọ kí ó má bá a jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ títa. 11Ṣùgbọ́n tí ọkùnrin kan bá kórìíra arákùnrin rẹ̀, tí ó sì lúgọ dè é, tí ó mú u tí o lù ú pa, tí ọkùnrin náà sì sálọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú wọ̀nyí, 12àwọn àgbàgbà ìlú rẹ yóò sì ránṣẹ́ pè é ìwọ, yóò sì mú un padà láti ìlú náà, wọn yóò sì fi í lé àwọn agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́ kí ó lè kú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.