Native Bible

Deuteronomy 17:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lénu ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta ni a ó pa ọkùnrin náà tí ó yẹ láti kú, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe pànìyàn nípasẹ̀ ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo.

Deuteronomy 17:6 in English

Deuteronomy 17:6 · Berean Standard Bible

On the testimony of two or three witnesses a man shall be put to death, but he shall not be executed on the testimony of a lone witness.

Context

4tí èyí sì dé etí ìgbọ́ ọ yín, kí ẹ wádìí ọ̀rọ̀ náà dájúdájú. Bí ó bá jẹ́ òtítọ́ tí ó sì hàn gbangba pé ó ti ṣe ohun ìríra yìí, ní Israẹli. 5Ẹ mú ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó ti ṣe ibi yìí wá sí ẹnu-ọ̀nà ibodè ìlú u yín, kí ẹ sọ ọ́ ní òkúta pa. 6Lénu ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta ni a ó pa ọkùnrin náà tí ó yẹ láti kú, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe pànìyàn nípasẹ̀ ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo. 7Àwọn ẹlẹ́rìí ni kí ó kọ́kọ́ gbọ́wọ́ lé e láti pa á. Lẹ́yìn èyí ni kí gbogbo ènìyàn dáwọ́jọ láti pa á. Nípa báyìí, ẹ̀yin yóò sì fọ ohun búburú náà mọ́ kúrò ní àárín yín. 8Bí ẹjọ́ bá wá sí ilé ẹjọ́ èyí tí ó nira jù láti dá, yálà ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni, ọ̀ràn dídá tàbí ìkanni-lábùkù, ẹ mú wọn lọ sí ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.