Native Bible

Deuteronomy 16:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ sun ún kí ẹ sì jẹ ẹ́ ní ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn. Ní àárọ̀, kí ẹ padà sí àgọ́ ọ yín.

Deuteronomy 16:7 in English

Deuteronomy 16:7 · Berean Standard Bible

And you shall roast it and eat it in the place the LORD your God will choose, and in the morning you shall return to your tents.

Context

5Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ìrékọjá náà ní ìlúkílùú kankan, tí Olúwa Ọlọ́run yín fi fún un yín 6bí kò ṣe ibi tí yóò yàn gẹ́gẹ́ bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀, níbẹ̀ ni ki ẹ ti ṣe ìrúbọ ìrékọjá náà ní ìrọ̀lẹ́ nígbà tí oòrùn bá ń wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìrántí ìgbà tí ẹ kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti. 7Ẹ sun ún kí ẹ sì jẹ ẹ́ ní ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn. Ní àárọ̀, kí ẹ padà sí àgọ́ ọ yín. 8Ọjọ́ mẹ́fà ní kí ẹ fi jẹ àkàrà aláìwú, ní ọjọ́ keje, ẹ pe àjọ kan fún Olúwa Ọlọ́run yín, kí ẹ má sì ṣe iṣẹ́ kankan. 9Ka ọ̀sẹ̀ méje láti ìgbà tí ẹ bá ti bẹ̀rẹ̀ sí fi dòjé ṣe ìkórè ọkà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.