Native Bible

Deuteronomy 16:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ tẹ̀lé ìdájọ́ òtítọ́ àní ìdájọ́ òtítọ́ nìkan, kí ẹ bá à lè gbé kí ẹ sì gba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín ń fún un yín.

Deuteronomy 16:20 in English

Deuteronomy 16:20 · Berean Standard Bible

Pursue justice, and justice alone, so that you may live, and you may possess the land that the LORD your God is giving you.

Context

18Ẹ yan àwọn adájọ́ àti àwọn olóyè fún ẹ̀yà a yín kọ̀ọ̀kan, ní gbogbo ìlú tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò fún un yín, wọ́n sì gbọdọ̀ máa fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn. 19Ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúsàájú ènìyàn. Ìwọ kò gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ń fọ́ ojú ọlọ́gbọ́n, ó sì ń ba ọ̀rọ̀ olódodo jẹ́. 20Ẹ tẹ̀lé ìdájọ́ òtítọ́ àní ìdájọ́ òtítọ́ nìkan, kí ẹ bá à lè gbé kí ẹ sì gba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín ń fún un yín. 21Ẹ má ṣe ri ère òrìṣà Aṣerah sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ tí ẹ ti mọ fún Olúwa Ọlọ́run yín. 22Ẹ kò gbọdọ̀ gbé òkúta òrìṣà gbígbẹ́ kan kalẹ̀ fún ara yín, nítorí èyí ni Olúwa Ọlọ́run yín kórìíra.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.