Native Bible

Deuteronomy 15:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí ẹran ọ̀sìn kan bá ní àbùkù: bóyá ó yarọ, tàbí fọ́jú, tàbí tí ó ní èyíkéyìí àbùkù tó burú. Ẹ kò gbọdọ̀ fi rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run yín.

Deuteronomy 15:21 in English

Deuteronomy 15:21 · Berean Standard Bible

But if an animal has a defect, is lame or blind, or has any serious flaw, you must not sacrifice it to the LORD your God.

Context

19Gbogbo àkọ́bí tí o jẹ́ akọ nínú agbo màlúù rẹ ni kí o yà sọ́tọ̀ fún Olúwa, àti nínú agbo ewúrẹ́ bákan náà. Ẹ má ṣe fi àkọ́bí màlúù yín ṣiṣẹ́ rárá. Má ṣe rẹ́ irun àkọ́bí àgùntàn rẹ pẹ̀lú. 20Ní ọdọọdún ni kí ìwọ àti ìdílé rẹ máa jẹ ẹ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín níbi tí Òun yóò yàn. 21Bí ẹran ọ̀sìn kan bá ní àbùkù: bóyá ó yarọ, tàbí fọ́jú, tàbí tí ó ní èyíkéyìí àbùkù tó burú. Ẹ kò gbọdọ̀ fi rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run yín. 22Ẹ jẹ ẹ́ ní ìlú u yín. Àti ẹni tí a kà sí mímọ́ àti aláìmọ́ ni ó lè jẹ ẹ́ bí ìgbà tí a ń jẹ èsúró tàbí àgbọ̀nrín. 23Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, ẹ dà á síta bí omi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.