Deuteronomi 14:3
Deuteronomy 14:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ má ṣe jẹ ohun ìríra kankan.
Deuteronomy 14:3 in English
Deuteronomy 14:3 · Berean Standard Bible
You must not eat any detestable thing.
Context
1Ọmọ Olúwa Ọlọ́run yín ni ẹ̀yin jẹ́: nítorí náà, ẹ má ṣe ya ara yín ní abẹ. Ẹ má ṣe gé irun iwájú orí yín nítorí òkú. 2Nítorí pé ènìyàn mímọ́ ní ẹ jẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run yín, nínú gbogbo ènìyàn tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, Ọlọ́run ti yàn yín láti jẹ́ ìṣúra iyebíye rẹ̀. 3Ẹ má ṣe jẹ ohun ìríra kankan. 4Àwọn wọ̀nyí ni ẹranko tí ẹ lè máa jẹ: màlúù, àgùntàn àti ewúrẹ́, 5àgbọ̀nrín, èsúró, etu, àgóró, ẹfọ̀n, ìgalà àti àgùntàn igbó.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.