Deuteronomi 14:28
Deuteronomy 14:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní òpin ọdún mẹ́ta mẹ́ta, ẹ̀yin yóò mú gbogbo ìdámẹ́wàá ìre oko àwọn ọdún náà, kí ẹ kó wọn jọ ní ìlú yín.
Deuteronomy 14:28 in English
Deuteronomy 14:28 · Berean Standard Bible
At the end of every three years, bring a tenth of all your produce for that year and lay it up within your gates.
Context
26Fi owó náà ra ohunkóhun tí o bá fẹ́, màlúù, àgùntàn, wáìnì, tàbí ọtí líle, tàbí ohunkóhun tí o bá fẹ́. Kí ìwọ àti ìdílé rẹ sì jẹ ẹ́ níwájú Olúwa níbẹ̀ kí ẹ sì máa yọ̀. 27Ẹ má ṣe gbàgbé àwọn Lefi tí ó ń gbé nì ìlú yín, nítorí pé wọn kò ní ìpín kan tàbí ogún kan tí í ṣe tiwọn. 28Ní òpin ọdún mẹ́ta mẹ́ta, ẹ̀yin yóò mú gbogbo ìdámẹ́wàá ìre oko àwọn ọdún náà, kí ẹ kó wọn jọ ní ìlú yín. 29Kí àwọn Lefi (tí kò ní ìpín tàbí ogún tiwọn) àti àwọn àjèjì, àwọn aláìní baba, àti àwọn opó tí ń gbé ìlú yín lè wá, kí wọn sì jẹ kí wọn sì yó, kí Olúwa Ọlọ́run rẹ le è bùkún fún ọ, nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.