Deuteronomi 12:27
Deuteronomy 12:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ fi ẹbọ sísun yín kalẹ̀ lórí i pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run yín, àti ẹran àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ ọrẹ yín ni ki ẹ dà sí pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run yín, ṣùgbọ́n ẹ lè jẹ ẹran.
Deuteronomy 12:27 in English
Deuteronomy 12:27 · Berean Standard Bible
Present the meat and blood of your burnt offerings on the altar of the LORD your God. The blood of your other sacrifices must be poured out beside the altar of the LORD your God, but you may eat the meat.
Context
25Ẹ má ṣe jẹ ẹ́, kí ó bá à lè dára fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín, tí ń bọ̀ lẹ́yìn in yín. Nígbà yí ní ẹ tó ń ṣe ohun tí ó tọ̀nà lójú Olúwa. 26Ẹ mú àwọn ohun tí ẹ yà sọ́tọ̀ àti àwọn ẹ̀jẹ́ yín, kí ẹ sì lọ sí ibi tí Olúwa yóò yàn. 27Ẹ fi ẹbọ sísun yín kalẹ̀ lórí i pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run yín, àti ẹran àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ ọrẹ yín ni ki ẹ dà sí pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run yín, ṣùgbọ́n ẹ lè jẹ ẹran. 28Ẹ kíyèsára láti máa gbọ́rọ̀ sí gbogbo ìlànà tí mò ń fún un yín, kí o bá à dára fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín nígbà gbogbo, nítorí pé nígbà náà ní ẹ tó ń ṣe ohun tí ó dára tí ó sì tọ̀nà níwájú Olúwa Ọlọ́run yín. 29Olúwa Ọlọ́run yín yóò gé àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ fẹ́ lé kúrò tí ẹ sì fẹ́ gba ilẹ̀ wọn kúrò níwájú u yín. Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ bá ti lé wọn jáde tí ẹ sì ń gbé ilẹ̀ wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.