Deuteronomi 10:18
Deuteronomy 10:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó máa ń gbẹjọ́ aláìní baba àti opó rò, Ó fẹ́ràn àjèjì, Òun fi aṣọ àti oúnjẹ fún wọn.
Deuteronomy 10:18 in English
Deuteronomy 10:18 · Berean Standard Bible
He executes justice for the fatherless and widow, and He loves the foreigner, giving him food and clothing.
Context
16Ẹ kọ ọkàn yín ní ilà, kí ẹ má sì ṣe jẹ́ olórí kunkun mọ́ láti òní lọ. 17Torí pé Olúwa Ọlọ́run yín, ni Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti Olúwa àwọn olúwa. Ọlọ́run alágbára, tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù, tí kì í ṣe ojúsàájú kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀. 18Ó máa ń gbẹjọ́ aláìní baba àti opó rò, Ó fẹ́ràn àjèjì, Òun fi aṣọ àti oúnjẹ fún wọn. 19Ẹ gbọdọ̀ fẹ́ràn àwọn àjèjì, torí pé ẹ̀yin pẹ̀lú ti jẹ́ àjèjì rí ní Ejibiti. 20Ẹ bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run yín, ẹ sì máa sìn ín. Ẹ dìímú ṣinṣin, kí ẹ sì búra ní orúkọ rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.