Native Bible

Deuteronomy 10:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

àti láti máa kíyèsi àṣẹ àti ìlànà Olúwa tí mo ń fún ọ lónìí, fún ìre ara à rẹ.

Deuteronomy 10:13 in English

Deuteronomy 10:13 · Berean Standard Bible

and to keep the commandments and statutes of the LORD that I am giving you this day for your own good?

Context

11Olúwa sọ fún mi pé, “Lọ darí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọ̀nà wọn, kí wọn bá à lè wọ ilẹ̀ náà, kí wọn sì gba ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba wọn láti fún wọn.” 12Nísinsin yìí ìwọ Israẹli, kín ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ béèrè lọ́wọ́ rẹ? Bí kò ṣe kí ìwọ bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ àti láti máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti fẹ́ràn rẹ̀, láti fi gbogbo ọkàn rẹ sin Olúwa Ọlọ́run rẹ ọkàn àti àyà rẹ, 13àti láti máa kíyèsi àṣẹ àti ìlànà Olúwa tí mo ń fún ọ lónìí, fún ìre ara à rẹ. 14Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé Olúwa Ọlọ́run yín ni ó ni ọ̀run àní àwọn ọ̀run tó ga ju ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀. 15Síbẹ̀ Olúwa sì tún fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn fún àwọn baba ńlá a yín, Ó sì fẹ́ wọn Ó sì yan ẹ̀yin ọmọ wọn láti borí gbogbo orílẹ̀-èdè títí di òní.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.