Native Bible

Deuteronomy 10:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nísinsin yìí ìwọ Israẹli, kín ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ béèrè lọ́wọ́ rẹ? Bí kò ṣe kí ìwọ bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ àti láti máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti fẹ́ràn rẹ̀, láti fi gbogbo ọkàn rẹ sin Olúwa Ọlọ́run rẹ ọkàn àti àyà rẹ,

Deuteronomy 10:12 in English

Deuteronomy 10:12 · Berean Standard Bible

And now, O Israel, what does the LORD your God ask of you but to fear the LORD your God by walking in all His ways, to love Him, to serve the LORD your God with all your heart and with all your soul,

Context

10Mo tún dúró ní orí òkè náà fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, bí mo ti ṣe ní ìgbà àkọ́kọ́, Olúwa sì gbọ́ tèmi ní àkókò yìí bákan náà. Kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀ láti run yín. 11Olúwa sọ fún mi pé, “Lọ darí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọ̀nà wọn, kí wọn bá à lè wọ ilẹ̀ náà, kí wọn sì gba ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba wọn láti fún wọn.” 12Nísinsin yìí ìwọ Israẹli, kín ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ béèrè lọ́wọ́ rẹ? Bí kò ṣe kí ìwọ bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ àti láti máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti fẹ́ràn rẹ̀, láti fi gbogbo ọkàn rẹ sin Olúwa Ọlọ́run rẹ ọkàn àti àyà rẹ, 13àti láti máa kíyèsi àṣẹ àti ìlànà Olúwa tí mo ń fún ọ lónìí, fún ìre ara à rẹ. 14Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé Olúwa Ọlọ́run yín ni ó ni ọ̀run àní àwọn ọ̀run tó ga ju ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.