Native Bible

Daniel 9:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀, tí mo sì ń gba àdúrà, tí mo ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi àti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn Israẹli ènìyàn mi, tí mo sì ń mú ẹ̀bẹ̀ mi tọ Olúwa Ọlọ́run mi nítorí òkè mímọ́ rẹ.

Daniel 9:20 in English

Daniel 9:20 · Berean Standard Bible

While I was speaking, praying, confessing my sin and that of my people Israel, and presenting my petition before the LORD my God concerning His holy mountain—

Context

18Tẹ́ etí rẹ sílẹ̀, Ọlọ́run, kí o gbọ́; ya ojú rẹ sílẹ̀, kí o sì wo ìdahoro ìlú tí a ń fi orúkọ rẹ pè. Àwa kò gbé ẹ̀bẹ̀ wa kalẹ̀ níwájú u rẹ nítorí pé a jẹ́ olódodo, bí kò ṣe nítorí àánú ńlá rẹ. 19Olúwa, fetísílẹ̀! Olúwa, dáríjì! Olúwa, gbọ́ kí o sì ṣe é! Nítorí i tìrẹ, Ọlọ́run mi, má ṣe pẹ́ títí, nítorí ìlú rẹ àti àwọn ènìyàn rẹ ń jẹ́ orúkọ mọ́ ọ lára.” 20Bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀, tí mo sì ń gba àdúrà, tí mo ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi àti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn Israẹli ènìyàn mi, tí mo sì ń mú ẹ̀bẹ̀ mi tọ Olúwa Ọlọ́run mi nítorí òkè mímọ́ rẹ. 21Bí mo ṣe ń gba àdúrà náà lọ́wọ́, Gabrieli ọkùnrin tí mo rí nínú ìran ìṣáájú, yára kánkán wá sí ọ̀dọ̀ mi ní àkókò ẹbọ àṣálẹ́. 22Ó jẹ́ kí ó yé mi, ó sì wí fún mi pé, “Daniẹli, mo wá láti jẹ́ kí o mọ̀ kí o sì ní òye.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.