Native Bible

Daniel 7:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ẹranko kìn-ín-ní dàbí i kìnnìún, ó sì ní ìyẹ́ apá a idì, mo sì wò títí a fi fa ìyẹ́ apá rẹ̀ náà tu, a sì gbé e sókè kúrò ní ilẹ̀, a mú kí ó fi ẹsẹ̀ dúró bí ènìyàn, a sì fi àyà ènìyàn fún un.

Daniel 7:4 in English

Daniel 7:4 · Berean Standard Bible

The first beast was like a lion, and it had the wings of an eagle. I watched until its wings were torn off and it was lifted up from the ground and made to stand on two feet like a man, and given the mind of a man.

Context

2Daniẹli sọ pé, “Nínú ìran mi lóru mo wò ó, mo sì rí afẹ́fẹ́ ọ̀run mẹ́rin tí ó ń ru omi Òkun ńlá sókè. 3Ẹranko ńlá mẹ́rin tí ó yàtọ̀ sí ara wọn, jáde láti inú Òkun náà. 4“Ẹranko kìn-ín-ní dàbí i kìnnìún, ó sì ní ìyẹ́ apá a idì, mo sì wò títí a fi fa ìyẹ́ apá rẹ̀ náà tu, a sì gbé e sókè kúrò ní ilẹ̀, a mú kí ó fi ẹsẹ̀ dúró bí ènìyàn, a sì fi àyà ènìyàn fún un. 5“Mo sì tún rí ẹranko kejì, ó rí bí irú ẹranko ńlá beari kan tí ó ń gbé ilẹ̀ òtútù; o gbé ara sókè ní apá kan, ó sì ní egungun ìhà mẹ́ta láàrín ẹ̀yìn in rẹ̀, wọ́n sì sọ fún un pé, ‘Dìde kí o sì jẹ ẹran tó pọ̀!’ 6“Lẹ́yìn ìgbà náà, mo tún rí ẹranko kẹta ó rí bí àmọ̀tẹ́kùn. Ẹranko náà ní ìyẹ́ bí i ti ẹyẹ ní ẹ̀yìn, ó sì ní orí mẹ́rin, a sì fún un ní agbára láti ṣe ìjọba.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.