Native Bible

Daniel 7:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹranko ńlá mẹ́rin tí ó yàtọ̀ sí ara wọn, jáde láti inú Òkun náà.

Daniel 7:3 in English

Daniel 7:3 · Berean Standard Bible

Then four great beasts came up out of the sea, each one different from the others:

Context

1Ní ọdún àkọ́kọ́ Belṣassari ọba Babeli, Daniẹli lá àlá kan, ìran náà sì wá sí ọkàn an rẹ̀ bí ó ṣe sùn sórí ibùsùn un rẹ̀, ó sì kọ àlá náà sílẹ̀. 2Daniẹli sọ pé, “Nínú ìran mi lóru mo wò ó, mo sì rí afẹ́fẹ́ ọ̀run mẹ́rin tí ó ń ru omi Òkun ńlá sókè. 3Ẹranko ńlá mẹ́rin tí ó yàtọ̀ sí ara wọn, jáde láti inú Òkun náà. 4“Ẹranko kìn-ín-ní dàbí i kìnnìún, ó sì ní ìyẹ́ apá a idì, mo sì wò títí a fi fa ìyẹ́ apá rẹ̀ náà tu, a sì gbé e sókè kúrò ní ilẹ̀, a mú kí ó fi ẹsẹ̀ dúró bí ènìyàn, a sì fi àyà ènìyàn fún un. 5“Mo sì tún rí ẹranko kejì, ó rí bí irú ẹranko ńlá beari kan tí ó ń gbé ilẹ̀ òtútù; o gbé ara sókè ní apá kan, ó sì ní egungun ìhà mẹ́ta láàrín ẹ̀yìn in rẹ̀, wọ́n sì sọ fún un pé, ‘Dìde kí o sì jẹ ẹran tó pọ̀!’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.