Daniẹli 7:17
Daniel 7:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
‘Àwọn ẹranko ńlá mẹ́rin yìí, ni ìjọba mẹ́rin tí yóò dìde ní ayé.
Daniel 7:17 in English
Daniel 7:17 · Berean Standard Bible
‘These four great beasts are four kings who will arise from the earth.
Context
15“Ọkàn èmi Daniẹli, dàrú, ìran tí ó wá sọ́kàn mi dẹ́rùbà mí. 16Mo lọ bá ọ̀kan nínú àwọn tí ó dúró níbẹ̀, mo sì bi í léèrè òtítọ́ ìtumọ̀ nǹkan wọ̀nyí.
“Ó sọ fún mi, ó sì túmọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí fún mi: 17‘Àwọn ẹranko ńlá mẹ́rin yìí, ni ìjọba mẹ́rin tí yóò dìde ní ayé. 18Ṣùgbọ́n, ẹni mímọ́ ti Ọ̀gá-ògo ni yóò gba ìjọba náà, yóò sì jogún un rẹ títí láé àti títí láéláé.’ 19“Nígbà náà, ni mo fẹ́ mọ ìtumọ̀ òtítọ́ ẹranko kẹrin, tí ó yàtọ̀ sí àwọn yòókù, èyí tí ó dẹ́rùba ni gidigidi, tí ó ní eyín irin àti èékánná idẹ, ẹranko tí ó ń run tí ó sì ń pajẹ, tí ó sì ń fi ẹsẹ̀ tẹ èyí tókù mọ́lẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.