Native Bible

Daniel 4:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Báwo ni àmì rẹ̀ ti tóbi tó, báwo ni ìyanu rẹ̀ ṣe pọ̀ tó! Ìjọba rẹ̀, ìjọba títí ayé ni; ilẹ̀ ọba rẹ̀ láti ìran dé ìran ni.

Daniel 4:3 in English

Daniel 4:3 · Berean Standard Bible

How great are His signs, how mighty His wonders! His kingdom is an eternal kingdom; His dominion endures from generation to generation.

Context

1Nebukadnessari ọba, sí gbogbo ènìyàn, orílẹ̀ àti onírúurú èdè, tí ó ń gbé ní àgbáyé. Kí àlàáfíà máa pọ̀ sí i fún un yín. Kí ẹ ṣe rere tó pọ̀! 2Ó jẹ́ ìdùnnú fún mi láti fi iṣẹ́ àmì àti ìyanu tí Ọlọ́run Ọ̀gá-Ògo ti ṣe fún mi hàn. 3Báwo ni àmì rẹ̀ ti tóbi tó, báwo ni ìyanu rẹ̀ ṣe pọ̀ tó! Ìjọba rẹ̀, ìjọba títí ayé ni; ilẹ̀ ọba rẹ̀ láti ìran dé ìran ni. 4Èmi Nebukadnessari wà ní ààfin mi, pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn àti àlàáfíà. 5Mo lá àlá kan èyí tí ó bà mí lẹ́rù. Nígbà tí mo wà lórí ibùsùn mi, ìran tí ó jáde lọ́kàn mi dẹ́rùbà mí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.