Native Bible

Daniel 3:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n sọ fún ọba Nebukadnessari pé, “Kí ọba kí ó pẹ́.

Daniel 3:9 in English

Daniel 3:9 · Berean Standard Bible

saying to King Nebuchadnezzar, “O king, may you live forever!

Context

7Nítorí náà, bí wọ́n ṣe gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókùn, ìpè àti onírúurú orin, gbogbo ènìyàn, orílẹ̀-èdè, àti èdè gbogbo wólẹ̀, wọ́n sì fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ọba Nebukadnessari gbé kalẹ̀. 8Ní àsìkò yìí ni àwọn awòràwọ̀ bọ́ síwájú, wọ́n sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ará Juda. 9Wọ́n sọ fún ọba Nebukadnessari pé, “Kí ọba kí ó pẹ́. 10Ìwọ ọba ti pàṣẹ pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókùn, ìpè àti onírúurú orin gbọdọ̀ wólẹ̀ kí ó fi orí balẹ̀ fún ère wúrà 11àti ẹnikẹ́ni tí kò bá wólẹ̀, kí ó foríbalẹ̀, a ó sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ sínú iná ìléru.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.