Native Bible

Daniel 2:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni Daniẹli padà lọ sí ilé e rẹ̀, ó sì sọ fún àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ Hananiah, Miṣaeli àti Asariah.

Daniel 2:17 in English

Daniel 2:17 · Berean Standard Bible

Then Daniel returned to his house and explained the matter to his friends Hananiah, Mishael, and Azariah,

Context

15Ó béèrè lọ́wọ́ olórí àwọn olùṣọ́ ọba wí pé, “Èéṣe tí àṣẹ ọba fi yá kánkán bẹ́ẹ̀?” Arioku sì ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ náà fún Daniẹli. 16Nígbà náà ni Daniẹli wọlé tọ ọba lọ, ó sì tọrọ kí ọba fún òun ní ààyè, òun yóò fi ìtumọ̀ àlá náà hàn fún ọba. 17Nígbà náà ni Daniẹli padà lọ sí ilé e rẹ̀, ó sì sọ fún àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ Hananiah, Miṣaeli àti Asariah. 18Ó sọ fún wọn pé kí wọn béèrè fún àánú Ọlọ́run, Olúwa ọ̀run, nítorí àṣírí yìí, kí Daniẹli pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ má ba ṣègbé pẹ̀lú àwọn ọlọ́gbọ́n Babeli yòókù, tí ó wà ní Babeli. 19Ní òru, àṣírí náà hàn sí Daniẹli ní ojú ìran. Nígbà náà ni Daniẹli fi ògo fún Ọlọ́run ọ̀run

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.