Native Bible

Daniel 12:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni a ó fọ̀ mọ́, wọn yóò wà láìlábàwọ́n, a ó sì tún wọn ṣe, ṣùgbọ́n àwọn ẹni búburú yóò máa ṣe búburú lọ, kò sí ẹni búburú tí òye yóò yé ṣùgbọ́n òye yóò yé àwọn ọlọ́gbọ́n.

Daniel 12:10 in English

Daniel 12:10 · Berean Standard Bible

Many will be purified, made spotless, and refined, but the wicked will continue to act wickedly. None of the wicked will understand, but the wise will understand.

Context

8Èmi gbọ́, ṣùgbọ́n kò yé mi. Nígbà náà ni mo béèrè pé, “Olúwa mi, kí ni yóò jẹ́ àbábọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí?” 9Ó sì dáhùn pé, “Máa lọ ní ọ̀nà rẹ, Daniẹli nítorí tí a ti pa ọ̀rọ̀ náà dé, a sì ti fi èdìdì dì í di ìgbà ìkẹyìn. 10Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni a ó fọ̀ mọ́, wọn yóò wà láìlábàwọ́n, a ó sì tún wọn ṣe, ṣùgbọ́n àwọn ẹni búburú yóò máa ṣe búburú lọ, kò sí ẹni búburú tí òye yóò yé ṣùgbọ́n òye yóò yé àwọn ọlọ́gbọ́n. 11“Láti àkókò tí a ó mú ẹbọ ojoojúmọ́ kúrò, tí a ó sì gbé ìríra tí ó ń fa ìsọdahoro kalẹ̀ yóò sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún àti igba lé àádọ́rùn-ún ọjọ́ (1,290). 12Ìbùkún ni fún ẹni tí ó dúró, ti ó sì di òpin ẹgbẹ̀rún àti ọ̀ọ́dúnrún lé àrùndínlógójì (1,335) ọjọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.