Native Bible

Daniel 11:33 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Àwọn tí ó mòye yóò máa kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n fún ìgbà díẹ̀, wọn yóò máa ṣubú nípa idà tàbí kí a jó wọn tàbí ìgbèkùn tàbí nípa ìkógun.

Daniel 11:33 in English

Daniel 11:33 · Berean Standard Bible

Those with insight will instruct many, though for a time they will fall by sword or flame, or be captured or plundered.

Context

31“Agbára ọmọ-ogun rẹ̀ yóò dìde láti ba ohun mímọ́ ilé olódi tẹmpili jẹ́, yóò sì pa ẹbọ ojoojúmọ́ rẹ́. Nígbà náà ni wọn yóò gbé ìríra tí ó fa ìsọdahoro kalẹ̀. 32Pẹ̀lú irú àwọn tí ń ṣe búburú sí májẹ̀mú ní yóò fi ọ̀rọ̀ ìpọ́nni mú ṣọ̀tẹ̀, ṣùgbọ́n, àwọn tí ó mọ Ọlọ́run wọn yóò mú ọkàn le. Wọn yóò sì máa ṣe iṣẹ́ agbára. 33“Àwọn tí ó mòye yóò máa kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n fún ìgbà díẹ̀, wọn yóò máa ṣubú nípa idà tàbí kí a jó wọn tàbí ìgbèkùn tàbí nípa ìkógun. 34Nígbà tí wọ́n bá ṣubú, wọn yóò rí ìrànlọ́wọ́ díẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tó ṣe aláìṣòótọ́ yóò sì darapọ̀ mọ́ wọn. 35Lára àwọn tí ó mòye yóò kọsẹ̀, nítorí kí a ba à tún wọn ṣe, wọ́n di mímọ́ àti aláìlábàwọ́n títí di ìgbà ìkẹyìn nítorí yóò sì wá ní àkókò tí a yàn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.