Daniẹli 11:32
Daniel 11:32 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Pẹ̀lú irú àwọn tí ń ṣe búburú sí májẹ̀mú ní yóò fi ọ̀rọ̀ ìpọ́nni mú ṣọ̀tẹ̀, ṣùgbọ́n, àwọn tí ó mọ Ọlọ́run wọn yóò mú ọkàn le. Wọn yóò sì máa ṣe iṣẹ́ agbára.
Daniel 11:32 in English
Daniel 11:32 · Berean Standard Bible
With flattery he will corrupt those who violate the covenant, but the people who know their God will firmly resist him.
Context
30Nítorí pé, ọkọ̀ ojú omi àwọn ilẹ̀ etídò ìwọ̀-oòrùn yóò takò ó, ọkàn rẹ̀ yóò sì pami. Nígbà náà, ni yóò padà, yóò sì bínú sí májẹ̀mú mímọ́, yóò sì padà, yóò sì fi ojúrere hàn sí àwọn tí ó kọ májẹ̀mú mímọ́ náà. 31“Agbára ọmọ-ogun rẹ̀ yóò dìde láti ba ohun mímọ́ ilé olódi tẹmpili jẹ́, yóò sì pa ẹbọ ojoojúmọ́ rẹ́. Nígbà náà ni wọn yóò gbé ìríra tí ó fa ìsọdahoro kalẹ̀. 32Pẹ̀lú irú àwọn tí ń ṣe búburú sí májẹ̀mú ní yóò fi ọ̀rọ̀ ìpọ́nni mú ṣọ̀tẹ̀, ṣùgbọ́n, àwọn tí ó mọ Ọlọ́run wọn yóò mú ọkàn le. Wọn yóò sì máa ṣe iṣẹ́ agbára. 33“Àwọn tí ó mòye yóò máa kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n fún ìgbà díẹ̀, wọn yóò máa ṣubú nípa idà tàbí kí a jó wọn tàbí ìgbèkùn tàbí nípa ìkógun. 34Nígbà tí wọ́n bá ṣubú, wọn yóò rí ìrànlọ́wọ́ díẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tó ṣe aláìṣòótọ́ yóò sì darapọ̀ mọ́ wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.