Native Bible

Daniel 11:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ní àsìkò tí a yàn, yóò gbógun sí gúúsù lẹ́ẹ̀kan sí i, ṣùgbọ́n ní ìgbà yí àyọríṣí yóò yàtọ̀ sí ti ìṣáájú.

Daniel 11:29 in English

Daniel 11:29 · Berean Standard Bible

At the appointed time he will invade the South again, but this time will not be like the first.

Context

27Àwọn ọba méjèèjì, ọkàn wọn tẹ̀ sí búburú, wọn yóò jókòó lórí tábìlì kan, wọn yóò máa parọ́ sí ara wọn, ṣùgbọ́n kò ní yọrí sí nǹkan kan nítorí òpin yóò wá ní àsìkò tí a yàn. 28Ọba àríwá yóò padà sí ilẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀, ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ yóò lòdì sí májẹ̀mú mímọ́, yóò sì ṣiṣẹ́ lòdì sí i, yóò sì padà sí orílẹ̀-èdè òun fúnra rẹ̀. 29“Ní àsìkò tí a yàn, yóò gbógun sí gúúsù lẹ́ẹ̀kan sí i, ṣùgbọ́n ní ìgbà yí àyọríṣí yóò yàtọ̀ sí ti ìṣáájú. 30Nítorí pé, ọkọ̀ ojú omi àwọn ilẹ̀ etídò ìwọ̀-oòrùn yóò takò ó, ọkàn rẹ̀ yóò sì pami. Nígbà náà, ni yóò padà, yóò sì bínú sí májẹ̀mú mímọ́, yóò sì padà, yóò sì fi ojúrere hàn sí àwọn tí ó kọ májẹ̀mú mímọ́ náà. 31“Agbára ọmọ-ogun rẹ̀ yóò dìde láti ba ohun mímọ́ ilé olódi tẹmpili jẹ́, yóò sì pa ẹbọ ojoojúmọ́ rẹ́. Nígbà náà ni wọn yóò gbé ìríra tí ó fa ìsọdahoro kalẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.