Daniẹli 11:28
Daniel 11:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọba àríwá yóò padà sí ilẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀, ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ yóò lòdì sí májẹ̀mú mímọ́, yóò sì ṣiṣẹ́ lòdì sí i, yóò sì padà sí orílẹ̀-èdè òun fúnra rẹ̀.
Daniel 11:28 in English
Daniel 11:28 · Berean Standard Bible
The king of the North will return to his land with great wealth, but his heart will be set against the holy covenant; so he will do damage and return to his own land.
Context
26Àwọn tí ó jẹ nínú oúnjẹ ọba yóò gbìyànjú láti parun, a ó gbá ogun rẹ̀ dànù, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò ṣubú sí ogun. 27Àwọn ọba méjèèjì, ọkàn wọn tẹ̀ sí búburú, wọn yóò jókòó lórí tábìlì kan, wọn yóò máa parọ́ sí ara wọn, ṣùgbọ́n kò ní yọrí sí nǹkan kan nítorí òpin yóò wá ní àsìkò tí a yàn. 28Ọba àríwá yóò padà sí ilẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀, ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ yóò lòdì sí májẹ̀mú mímọ́, yóò sì ṣiṣẹ́ lòdì sí i, yóò sì padà sí orílẹ̀-èdè òun fúnra rẹ̀. 29“Ní àsìkò tí a yàn, yóò gbógun sí gúúsù lẹ́ẹ̀kan sí i, ṣùgbọ́n ní ìgbà yí àyọríṣí yóò yàtọ̀ sí ti ìṣáájú. 30Nítorí pé, ọkọ̀ ojú omi àwọn ilẹ̀ etídò ìwọ̀-oòrùn yóò takò ó, ọkàn rẹ̀ yóò sì pami. Nígbà náà, ni yóò padà, yóò sì bínú sí májẹ̀mú mímọ́, yóò sì padà, yóò sì fi ojúrere hàn sí àwọn tí ó kọ májẹ̀mú mímọ́ náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.