Native Bible

Daniel 11:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ́yìn èyí, yóò sì yí padà sí ìlú olódi ti orílẹ̀-èdè òun fúnra rẹ̀, ṣùgbọ́n yóò kọsẹ̀ yóò sì ṣubú, a kì yóò sì rí i mọ́.

Daniel 11:19 in English

Daniel 11:19 · Berean Standard Bible

After this, he will turn back toward the fortresses of his own land, but he will stumble and fall and be no more.

Context

17Yóò pinnu láti wá pẹ̀lú agbára ìjọba rẹ̀, yóò sì ní májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú ọba gúúsù yóò sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ fún un láti fẹ́ ẹ ní ìyàwó nítorí kí ó lè gba ìjọba, ṣùgbọ́n ète rẹ̀ yìí kì yóò dúró tàbí ṣe ìrànlọ́wọ́ fún un. 18Nígbà náà ni yóò yí ara padà sí ilẹ̀ etí Òkun, yóò mú ọ̀pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n aláṣẹ kan yóò mú òpin bá àfojúdi rẹ̀, yóò sì yí àfojúdi rẹ̀ padà sí orí rẹ̀. 19Lẹ́yìn èyí, yóò sì yí padà sí ìlú olódi ti orílẹ̀-èdè òun fúnra rẹ̀, ṣùgbọ́n yóò kọsẹ̀ yóò sì ṣubú, a kì yóò sì rí i mọ́. 20“Arọ́pò rẹ̀ yóò rán agbowó orí kan jáde láti fi ìdí ipò ọlá ọba múlẹ̀ ṣùgbọ́n ní ìwọ̀n ọdún díẹ̀, a ó pa á run, kì yóò jẹ́ nípa ìbínú tàbí nínú ogun. 21“Ẹni tí kò níláárí kan yóò rọ́pò rẹ̀, ẹni tí a kò tí ì fi ọlá ọba fún rí. Yóò sì gbógun sí ìjọba nígbà tí ọkàn àwọn ènìyàn balẹ̀ láìbẹ̀rù, yóò sì gbà á pẹ̀lú àrékérekè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.